2 Chronicles 29:30 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọba ati àwọn ìjòyè pàṣẹ fún àwọn ọmọ Lefi pé kí wọ́n kọ orin ìyìn Dafidi ati ti Asafu, aríran. Wọ́n fi ayọ̀ kọ orin ìyìn náà, wọ́n wólẹ̀, wọ́n sì sin OLUWA.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Pẹlupẹlu Hesekiah ọba, ati awọn ijoye paṣẹ fun awọn ọmọ Lefi, lati fi ọ̀rọ Dafidi ati ti Asafu ariran, kọrin iyìn si Oluwa: nwọn si fi inu-didùn kọrin iyìn, nwọn si tẹri wọn ba, nwọn si sìn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Pẹ̀lúpẹ́lú Heṣekáyà ọba, àti àwọn ìjòyè pàṣẹ fún àwọn ọmọ Léfì, láti fi ọ̀rọ̀ Dáfídì àti ti Ásáfù aríran, kọrin ìyìn sí OLÚWA: wọ́n sì fi inú dídùn kọrin ìyìn, wọ́n sì tẹrí wọn ba, wọ́n sì sìn.