2 Chronicles 29:31 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Hesekaya bá sọ fún wọn pé: “Nisinsinyii tí ẹ ti ya ara yín sọ́tọ̀ fún OLUWA, ẹ wá, kí ẹ sì mú ọrẹ ati ẹbọ ọpẹ́ wá sí ilé OLUWA.” Ìjọ eniyan sì mú ọrẹ ati ẹbọ ọpẹ́ wá, àwọn tí wọ́n fẹ́ sì mú ẹbọ sísun wá.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni Hesekiah dahùn, o si wipe, Nisisiyi, ọwọ nyin kún fun ẹ̀bun fun Oluwa, ẹ ṣunmọ ihin, ki ẹ si mu ẹbọ ati ọrẹ-ọpẹ wá sinu ile Oluwa. Ijọ ẹnia si mu ẹbọ ati ọrẹ-ọpẹ wá; ati olukuluku ti ọkàn rẹ̀ fẹ, mu ẹbọ sisun wá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni Hesekíáyà dáhùn, ó sì wí pé, nísinsin yìí, ọwọ́ yín kún fún ẹ̀bùn fún OLÚWA, ẹ súnmọ ìhín, kí ẹ sì mú ẹbọ àti ọrẹ ọpẹ́ wá sínú ilé OLÚWA. Ìjọ ènìyàn sì mú ẹbọ àti ọrẹ-ọpẹ́ wá; àti olúkúlùkù tí ọkàn rẹ̀ fẹ́, mú ẹbọ sísun wá.