2 Chronicles 29:34 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn alufaa kò pọ̀ tó láti pa gbogbo ẹran náà, nítorí náà, kí ó tó di pé àwọn alufaa mìíràn yóo ya ara wọn sí mímọ́, àwọn arakunrin wọn, àwọn ọmọ Lefi, ràn wọ́n lọ́wọ́ títí iṣẹ́ náà fi parí. Àwọn ọmọ Lefi ṣe olóòótọ́ ní yíya ara wọn sí mímọ́ ju àwọn alufaa lọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn awọn alufa kò to, nwọn kò si le họ gbogbo awọn ẹran ẹbọ sisun na: nitorina awọn arakunrin wọn, awọn ọmọ Lefi ràn wọn lọwọ, titi iṣẹ na fi pari, ati titi awọn alufa iyokù fi yà ara wọn si mimọ́: nitori awọn ọmọ Lefi ṣe olõtọ li ọkàn jù awọn alufa lọ lati yà ara wọn si mimọ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n àwọn àlùfáà kò pọ̀ tó, wọn kò sì le bó gbogbo àwọn ẹran ẹbọ sísun náà: nítorí náà àwọn arákùnrin wọn, àwọn Lefi ràn wọ́n lọ́wọ́, títí iṣe náà fi parí, àti títí àwọn àlùfáà ìyókù fi yà wọ́n sí mímọ́: nítorí àwọn ọmọ Léfì ṣe olóòtọ́ ní ọkàn ju àwọn àlùfáà lọ láti ya ara wọn sí mímọ́.