2 Chronicles 29:35 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Yàtọ̀ sí ọpọlọpọ ẹbọ sísun, wọ́n fi ọ̀rá rú ẹbọ alaafia ati ẹbọ ohun mímu fún ẹbọ sísun. Bẹ́ẹ̀ ni iṣẹ́ ìsìn ninu ilé OLUWA ṣe tún bẹ̀rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati pẹlu, awọn ẹbọ sisun papọju, pẹlu ọra ẹbọ-alafia, pẹlu ẹbọ ohun-mimu fun ẹbọ sisun. Bẹ̃li a si to iṣẹ́-ìsin ile Oluwa li ẹsẹsẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àti pẹ̀lú, àwọn ẹbọ sísun pàpọ̀jù, pẹ̀lú ọ̀rá ẹbọ àlàáfíà, pẹ̀lú ẹbọ ohun-mímu fún ẹbọ sísun. Bẹ́ẹ̀ ni a sì tún dá ti iṣẹ́-ìsìn ilé OLÚWA sílẹ̀.