2 Chronicles 29:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó kó àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi jọ sí gbàgede tí ó wà ní apá ìlà oòrùn ilé Ọlọrun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si mu awọn alufa wá ati awọn ọmọ Lefi, o si kó wọn jọ si ita ila-õrun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì mú àwọn àlùfáà wá àti àwọn ọmọ Léfì, ó sì kó wọn jọ yíká ìta ìlà òorùn.