2 Chronicles 29:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó ní, “Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ọmọ Lefi, ẹ ya ara yín sí mímọ́, kí ẹ sì ya ilé OLUWA, Ọlọrun àwọn baba yín sí mímọ́ pẹlu. Ẹ kó gbogbo àwọn nǹkan ẹ̀gbin kúrò ninu ibi mímọ́,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si wi fun wọn pe, Ẹ gbọ́ temi, ẹnyin ọmọ Lefi; ẹ yà ara nyin si mimọ́ nisisiyi, ki ẹ si yà ile Oluwa Ọlọrun awọn baba nyin si mimọ́, ki ẹ si kó ohun aimọ́ na jade kuro ni ibi mimọ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì wí pé, “Ẹ gbọ́ tèmi, ẹ̀yin ọmọ Léfì! Ẹ ya ara yín sí mímọ́ nísinsin yìí kí ẹ sì ya ile OLÚWA Ọlọ́run sí mímọ́, kí ẹ sì kó ohun àìmọ́ bàbá jáde kúrò ní ibi mímọ́.