2 Chronicles 29:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí náà ni OLUWA ṣe bínú sí Juda ati Jerusalẹmu, ohun tí Ọlọrun fi wọ́n ṣe sì dẹ́rùba gbogbo eniyan. Wọ́n di ẹni ẹ̀gàn ati ẹni àrípòṣé, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti rí i lónìí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina ibinu Oluwa wà lori Juda ati Jerusalemu, o si fi wọn fun wàhala, ati iyanu ati ẹ̀sin, bi ẹnyin ti fi oju nyin ri.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà, ìbínú OLÚWA ti ru sókè wá sórí Júdà àti Jérúsálẹ́mù ó sì ti fi wọ́n ṣe ohun èlò fún wàhálà, àti ìyanu àti ẹ̀sín, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe fi ojú rẹ̀ rí i.