2 Chronicles 3:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Gígùn gbogbo ìyẹ́ kerubu mejeeji jẹ́ ogún igbọnwọ (mita 9). Ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu àwọn ìyẹ́ kerubu kinni keji jẹ́ igbọnwọ marun-un (mita 2¼), ọ̀kan ninu àwọn ìyẹ́ kerubu kinni nà kan ògiri ilé náà lẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, ìyẹ́ rẹ̀ keji tí òun náà jẹ́ igbọnwọ marun-un (mita 2¼), nà kan ìyẹ́ kerubu keji.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iyẹ awọn kerubu na si jẹ ogún igbọnwọ ni gigùn: iyẹ kan jẹ igbọnwọ marun, ti o kan ogiri ile na, iyẹ keji si jẹ igbọnwọ marun, ti o kan iyẹ kerubu keji.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Iye ìyẹ́ apá ìbú atẹ́lẹwọ́ lápapọ̀ ní ti kérúbù, jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́ ọ̀kan nínú ìyẹ́ apá ti kérúbù àkọ́kọ́ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní gígùn, ó sì farakan ògiri ilé OLÚWA. Nígbà tí ìyẹ́ apa kejì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-un ní gígùn ó sì, farakan ìyẹ́ apá kérúbù mìíràn.