2 Chronicles 3:17 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó gbé àwọn òpó náà kalẹ̀ níwájú tẹmpili, ọ̀kan ní ìhà àríwá, wọ́n ń pè é ní Jakini, ekeji ní ìhà gúsù, wọ́n ń pè é ní Boasi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si gbé awọn ọwọ̀n na ro niwaju ile Ọlọrun, ọkan li apa ọtún, ati ekeji li apa òsi, o si pe orukọ eyi ti mbẹ li apa ọtún ni Jakini, ati orukọ eyi ti mbẹ li apa òsi ni Boasi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó gbe òpó náà dúró níwájú ilé OLÚWA, ọ̀kan sí gúsù, pẹ̀lú ọ̀kan sí àríwá. Èyí ti gúsù, ó ṣe ní Jákínì àti èyí ti àríwá, ó ṣe ní Bóásì.