2 Chronicles 30:16 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí fi ara wọn sí ipò tí ó yẹ kí wọ́n wà, gẹ́gẹ́ bí òfin Mose, eniyan Ọlọrun; àwọn alufaa bẹ̀rẹ̀ sí wọ́n ẹ̀jẹ̀ tí wọ́n gbà lọ́wọ́ àwọn ọmọ Lefi sí orí pẹpẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si duro ni ipò wọn, bi ètò wọn gẹgẹ bi ofin Mose, enia Ọlọrun: awọn alufa wọ́n ẹ̀jẹ na, ti nwọn gbà lọwọ awọn ọmọ Lefi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n sì dúró ní ipò wọn, bí ètò wọn gẹ́gẹ́ bí òfin Mósè, ènìyàn Ọlọ́run: àwọn àlùfáà wọ́n ẹ̀jẹ̀ náà, tí wọ́n gbà lọ́wọ́ àwọn ọmọ Léfì.