2 Chronicles 30:21 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n wà ní Jerusalẹmu pa Àjọ Àìwúkàrà mọ́ fún ọjọ́ meje pẹlu ayọ̀ ńlá. Àwọn ọmọ Lefi ati àwọn alufaa ń kọrin ìyìn sí OLUWA lojoojumọ pẹlu gbogbo agbára wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ọmọ Israeli ti a ri ni Jerusalemu fi ayọ̀ nla pa ajọ àkara alaiwu mọ́ li ọjọ meje: awọn ọmọ Lefi, ati awọn alufa yìn Oluwa lojojumọ, nwọn nfi ohun-elo olohùn goro kọrin si Oluwa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí a rí ní Jérúsálẹ́mù fi ayọ̀ ńlá pa àjọ àkàrà aláìwú mọ́ ní ọjọ́ méje: àwọn ọmọ Léfì, àti àwọn àlùfáà yin OLÚWA lójojúmọ́, wọ́n ń fi ohun èlò olóhùn gooro kọrin sí OLÚWA.