2 Chronicles 30:22 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Hesekaya gba àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n ṣe dáradára ninu iṣẹ́ OLUWA níyànjú. Àwọn eniyan náà jẹ àsè àjọ náà fún ọjọ́ meje, wọ́n ń rú ẹbọ alaafia, wọ́n sì ń dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA Ọlọrun àwọn baba wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Hesekiah sọ̀rọ itunu fun gbogbo awọn ọmọ Lefi, ti o loye ni ìmọ rere Oluwa: ijọ meje ni nwọn fi jẹ àse na, nwọn nru ẹbọ alafia, nwọn si nfi ohùn rara dupẹ fun Oluwa, Ọlọrun awọn baba wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Heṣekáyà sọ̀rọ̀ ìtùnú fún gbogbo àwọn ọmọ Léfì, tí ó lóye ní ìmọ̀ rere OLÚWA: ọjọ́ méje ni wọ́n fi jẹ àṣè náà wọ́n rú ẹbọ àlàáfíà, wọ́n sì ń fi ohùn rara dúpẹ́ fún OLÚWA, Ọlọ́run àwọn baba wọn.