2 Chronicles 30:24 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Hesekaya, ọba fún àwọn eniyan náà ní ẹgbẹrun (1,000) akọ mààlúù ati ẹẹdẹgbaarin (7,000) aguntan láti fi rúbọ. Àwọn ìjòyè náà fún àwọn eniyan ní ẹgbẹrun (1,000) akọ mààlúù, ati ẹgbaarun (10,000) aguntan. Ọpọlọpọ àwọn alufaa ni wọ́n wá, tí wọ́n sì ya ara wọn sí mímọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori Hesekiah, ọba Juda, ta ijọ enia na li ọrẹ, ẹgbẹrun akọ-malu, ati ẹ̃dẹgbãrun àgutan: ọ̀pọlọpọ ninu awọn alufa si yà ara wọn si mimọ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí Heṣekáyà, ọba Júdà, ta ìjọ ènìyàn náà ní ọrẹ, ẹgbẹ̀rún akọ màlúù, àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárún àgùntàn: Ọ̀pọlọpọ̀ nínú àwọn àlùfáà sì ya ara wọn sí mímọ́.