2 Chronicles 30:25 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Gbogbo àwọn ará Juda, ati àwọn alufaa, ati àwọn ọmọ Lefi, ati àwọn onílé ati àwọn àlejò tí wọ́n wá láti ilẹ̀ Israẹli ati àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ Juda, gbogbo wọn ni wọ́n kún fún ayọ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Gbogbo ijọ-enia Juda pẹlu awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi, ati gbogbo ijọ-enia ti o ti inu Israeli jade wá, ati awọn àlejo ti o ti ilẹ Israeli jade wá, ati awọn ti ngbe Juda yọ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbogbo ìjọ ènìyàn Júdà pẹ̀lú àwọn àlùfaà àti àwọn ọmọ Léfì, àti gbogbo ìjọ ènìyàn tí ó ti inú Ísírẹ́lì jáde wá, àti àwọn àlejò tí ó ti ilẹ̀ Ísírẹ́lì jáde wá, àti àwọn tí ń gbé Júdà yọ̀.