2 Chronicles 30:27 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi dìde, wọ́n súre fún àwọn eniyan; OLUWA gbọ́ ohùn wọn, adura wọn sì gòkè lọ sí ibùgbé mímọ́ rẹ̀ lọ́run.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana li awọn alufa, awọn ọmọ Lefi dide, nwọn si sure fun awọn enia na: a si gbọ́ ohùn wọn, adura wọn si gòke lọ si ibugbe mimọ́ rẹ̀, ani si ọrun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Léfì dìde, wọ́n sì súre fún àwọn ènìyàn náà: a sì gbọ́ ohùn wọn, àdúrà wọn sì gòkè lọ si ibùgbé mímọ́ rẹ̀, àni sí ọ̀run.