2 Chronicles 30:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọ́n bá pàṣẹ pé kí wọ́n kéde jákèjádò gbogbo ilẹ̀ Israẹli láti Beeriṣeba títí dé Dani, pé kí àwọn eniyan wá sí Jerusalẹmu láti pa Àjọ Ìrékọjá mọ́ fún OLUWA Ọlọrun Israẹli; nítorí pé wọn kò tíì ṣe Àjọ Ìrékọjá náà pẹlu ọ̀pọ̀ eniyan gẹ́gẹ́ bí ìlànà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bẹ̃ni nwọn fi aṣẹ kan lelẹ, lati kede ká gbogbo Israeli, lati Beer-ṣeba ani titi de Dani, lati wá ipa ajọ irekọja mọ́ si Oluwa Ọlọrun Israeli ni Jerusalemu: nitori nwọn kò pa a mọ́ li ọjọ pupọ gẹgẹ bi a ti kọ ọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n fi àṣẹ kan lélẹ̀, láti kéde ká gbogbo Ísírẹ́lì láti Beerí-sébà àní títí dé Dánì, láti wá pa àjọ ìrékọjá mọ́ sí OLÚWA Ọlọ́run Ísírẹ́lì ní Jérúsálẹ́mù: nítorí wọn kò pa á mọ́ ní ọjọ́ púpọ̀ gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́.