2 Chronicles 30:7 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹ má dàbí àwọn baba yín ati àwọn arakunrin yín tí wọ́n ṣe alaiṣootọ sí OLUWA, Ọlọrun àwọn baba wọn, tí ó sì sọ ilẹ̀ wọn di ahoro bí ẹ ti rí i yìí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki ẹnyin ki o má si ṣe dabi awọn baba nyin, ati bi awọn arakunrin nyin, ti o dẹṣẹ si Oluwa, Ọlọrun awọn baba wọn, nitorina li o ṣe fi wọn fun idahoro, bi ẹnyin ti ri.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kí ẹ̀yin kí ó má sì ṣe dàbí àwọn baba yín, àti bí àwọn arákùnrin yín tí ó dẹ́sẹ̀ sí OLÚWA, Ọlọ́run àwọn baba wọn, nítorí náà ní ó ṣe fi wọ́n fún ìdahoro bí ẹ̀yin ti rí.