2 Chronicles 30:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bí ẹ bá pada sọ́dọ̀ OLUWA, àwọn arakunrin yín ati àwọn ọmọ yín yóo rí àánú lọ́dọ̀ àwọn tí ó kó wọn lẹ́rú, wọn yóo sì dá wọn pada sí ilẹ̀ yìí. Nítorí olóore ọ̀fẹ́ ati aláàánú ni OLUWA Ọlọrun yín, kò ní kẹ̀yìn si yín bí ẹ bá pada sọ́dọ̀ rẹ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori bi ẹnyin ba tun yipada si Oluwa, awọn arakunrin nyin, ati awọn ọmọ nyin, yio ri ãnu niwaju awọn ti o kó wọn ni ìgbekun lọ, ki nwọn ki o le tun pada wá si ilẹ yi: nitori Oluwa Ọlọrun nyin, oniyọ́nu ati alãnu ni, kì yio si yi oju rẹ̀ pada kuro lọdọ nyin, bi ẹnyin ba pada sọdọ rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí bí ẹ̀yin bá tún yípadà sí OLÚWA, àwọn arákùnrin yín, àti àwọn ọmọ yín, yóò rí àánú níwájú àwọn tí ó kó wọn ní ìgbèkùn lọ, kí wọn kí ó lè tún padà wá sí ilẹ̀ yí: nítorí OLÚWA Ọlọ́run yín, oníyọ́nú àti aláàánú ni, kì yóò sì yí ojú rẹ̀ padà kúrò lọ́dọ̀ yín, bí ẹ̀yin bá padà sọ́dọ̀ rẹ̀.”