2 Chronicles 31:1 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí wọ́n parí ayẹyẹ wọnyi, gbogbo àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n wá síbi àjọ náà lọ sí àwọn ìlú Juda, wọ́n fọ́ gbogbo òpó oriṣa, ati gbogbo igbó oriṣa Aṣera, wọ́n wó gbogbo àwọn pẹpẹ palẹ̀ ní gbogbo ilẹ̀ Juda, ti Bẹnjamini, ti Efuraimu ati ti Manase. Nígbà tí wọ́n fọ́ gbogbo wọn túútúú tán, wọ́n pada lọ sí ìlú wọn, olukuluku sì lọ sí orí ilẹ̀ rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
NJẸ nigbati gbogbo eyi pari, gbogbo Israeli ti a ri nibẹ jade lọ si ilu Juda wọnni, nwọn si fọ́ awọn ere tũtu, nwọn si bẹ́ igbo òriṣa lulẹ, nwọn si bì ibi giga wọnni ati awọn pẹpẹ ṣubu, ninu gbogbo Juda ati Benjamini, ni Efraimu pẹlu ati Manasse, titi nwọn fi pa gbogbo wọn run patapata. Nigbana ni gbogbo awọn ọmọ Israeli yipada, olukuluku si ilẹ-ini rẹ̀ si ilu wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí gbogbo nǹkan wọ̀nyí ti dé òpin, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí ó wà níbẹ̀ jáde lọ sí àwọn ìlú Júdà, wọ́n fọ́ àwọn òkúta ìyàsọ́tọ̀ sí wẹ́wẹ́, wọ́n gé àwọn òpó Áṣérà lulẹ̀. Wọ́n ba àwọn ibi gíga jẹ́ àti àwọn pẹpẹ Jákè jádò Júdà àti Bẹ́ńjámínì àti ní Éfíráimù àti Mánásè. Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti pa gbogbo wọn run, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì padà sí ìlú wọn àti sí nǹkan ìní wọn.