2 Chronicles 31:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Asaraya, olórí alufaa, láti ìdílé Sadoku dá a lóhùn pé: “Láti ìgbà tí àwọn eniyan ti bẹ̀rẹ̀ sí mú ẹ̀bùn wá sí ilé OLUWA ni a ti ń jẹ àjẹyó, tí ó sì ń ṣẹ́kù, nítorí pé OLUWA ti bukun àwọn eniyan rẹ̀, ni a fi ní àjẹṣẹ́kù tí ó pọ̀ tó yìí.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Asariah, olori alufa ti ile Sadoku, si da a lohùn o si wipe, Lati igba ti awọn enia bẹ̀rẹ si imu ọrẹ wá sinu ile Oluwa, awa ní to lati jẹ, a si kù pupọ silẹ: Oluwa sa ti bukún awọn enia rẹ̀; eyiti o kù ni iṣura nla yi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Sádókù sì dáhùn pé “Ní ìwọ̀n ìgbà tí àwọn ènìyàn ti bẹ̀rẹ̀ sí ní mú ìdáwó wọn wá sí ilé OLÚWA àti ní èyí tí yóò tó jẹ àti ọ̀pọ̀ láti tọ́jú pamọ́ nítorí OLÚWA ti bùkún àwọn ènìyàn rẹ̀, ó sì sẹ́kù lọ́pọ̀lọpọ̀.”