2 Chronicles 31:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọ́n ṣolóòótọ́ ní kíkó àwọn ẹ̀bùn, ati ìdámẹ́wàá àwọn ohun ìyàsọ́tọ̀ náà pamọ́. Konanaya, ọmọ Lefi, ni olórí àwọn tí wọn ń bojútó wọn, Ṣimei, arakunrin rẹ̀ ni igbákejì rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si mu awọn ọrẹ ati idamẹwa ati ohun ti a yà si mimọ́ wọ̀ ile wá nitõtọ: lori eyiti Kononiah, ọmọ Lefi, nṣe olori, Ṣimei arakunrin rẹ̀ si ni igbakeji.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà wọ́n fi tọkàntọkàn mú ìdáwó wọn wá ìdámẹ́wàá àti àwọn ẹ̀bùn yíyà sọ́tọ̀. Kónánáyà ará Léfì wà ní ìdí nǹkan wọ̀nyí àti arákùnrin rẹ̀ Ṣíméhì jẹ́ àtẹ̀lé e rẹ̀ lóyè.