2 Chronicles 31:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Kore, ọmọ Imina, ọmọ Lefi kan tí ń ṣọ́ ẹnu ọ̀nà ìlà oòrùn tẹmpili ni ó ń ṣe alákòóso ọrẹ àtinúwá tí wọ́n mú wá fún Ọlọrun. Òun ni ó sì ń pín àwọn ẹ̀bùn tí a yà sọ́tọ̀ fún OLUWA ati àwọn ọrẹ mímọ́ jùlọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati Kore, ọmọ Imna, ọmọ Lefi, adèna iha ila-õrun, li o wà lori awọn ọrẹ atinuwa Ọlọrun, lati pin ẹbọ ọrẹ Oluwa, ati ohun mimọ́ julọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kórè ọmọ ímínà ará Léfì Olùtọ́jú ẹnu ọ̀nà ìlà oòrùn, wà ní ìkáwọ́ àwọn ọrẹ àtinúwá tí a fi fún Ọlọ́run, pí pín ìdáwó tí a ṣe fún OLÚWA pẹ̀lú àwọn ẹ̀bùn tí a yà sọ́tọ̀