2 Chronicles 31:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Edẹni, Miniamini, ati Jeṣua, Ṣemaaya, Amaraya, ati Ṣekanaya, ń ràn án lọ́wọ́ ní gbogbo ìlú àwọn alufaa, wọ́n ń pín àwọn ẹ̀bùn náà láì ṣe ojuṣaaju àwọn arakunrin wọn, lọ́mọdé ati lágbà ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí;
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati labẹ ọwọ rẹ̀ ni Edeni, ati Miniamini, ati Jeṣua, ati Ṣemaiah, Amariah, ati Ṣekaniah, ninu ilu awọn alufa, lati fun awọn arakunrin wọn li ẹsẹsẹ, li otitọ, bi fun ẹni-nla, bẹ̃ni fun ẹni-kekere.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Édẹ́nì, Miníámínì, Jéṣúà, Ṣemáyà, Ámáríyà àti Ṣekánáyà ràn án lọ́wọ́ tọkàntọkàn nínú àwọn ìlú àwọn àlùfáà tí ń dáwó fún àwọn àlùfáà ẹlẹ́gbẹ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn, àgbà àti kékeré.