2 Chronicles 31:16 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
àfi àwọn ọkunrin, láti ẹni ọdún mẹta sókè, tí wọ́n ti kọ orúkọ wọn sílẹ̀ ní ìdílé ìdílé, gbogbo awọn tí wọ́n wọ ilé OLUWA gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ olukuluku ṣe gbà lójoojúmọ́, fun iṣẹ́ ìsìn wọn gẹ́gẹ́ bí ipò wọn, nípa ìpín wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Laika awọn ọkunrin, ti a kọ sinu iwe idile, lati ọmọ ọdun mẹta ati jù bẹ̃ lọ, fun olukuluku wọn ti o nwọ̀ inu ile Oluwa lọ, ìwọn tirẹ̀ lojojumọ, fun iṣẹ ìsin wọn, ninu ilana wọn, gẹgẹ bi ipa wọn;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní àfikún, wọ́n pín sí àwọn ọkùnrin àgbà ọdún mẹ́ta tàbi ọ̀pọ̀ tí orúkọ wọn wà nínu ìtàn ìdíle láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn. Gbogbo àwọn ti yóò wọ ilé OLÚWA láti ṣe oríṣìí iṣẹ́ ti a gbàwọ́n fún gẹ́gẹ́ bí ìgbẹ́kẹ̀lé wọn àti ìpín wọn.