2 Chronicles 31:18 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn alufaa kọ orúkọ wọn sílẹ̀ pẹlu àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ wọn, àwọn aya wọn, àwọn ọmọ wọn lọkunrin ati lobinrin gbogbo wọn patapata, nítorí pé wọ́n jẹ́ olóòótọ́ nípa pípa ara wọn mọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati fun awọn ti a kọ sinu iwe, gbogbo awọn ọmọ kekeke wọn, awọn aya wọn, ati awọn ọmọkunrin wọn, ati awọn ọmọbinrin wọn, ja gbogbo ijọ enia na: nitori ninu otitọ ni nwọn yà ara wọn si mimọ́ ninu iṣẹ mimọ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n fi gbogbo àwọn ọmọ kékèké sí i, àwọn ìyàwó, àti àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin gbogbo ará ìlu. Tí a kọ lẹ́sẹsẹ sínú ìtàn ìdílé yìí ti baba ńlá wọn fún ìrántí. Nítorí tí wọ́n ṣe òtítọ́ ní yíya ara wọn sí ọ̀tọ̀.