2 Chronicles 31:19 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ninu àwọn alufaa tí wọ́n wà ní ìlú àwọn ìran Aaroni ní ilẹ̀ gbogbogbòò ati ninu ìletò wọn, ni àwọn olóòótọ́ wà, tí wọ́n yàn láti máa pín oúnjẹ fún olukuluku ninu àwọn alufaa ati àwọn tí orúkọ wọn wà ninu àkọsílẹ̀ ìdílé àwọn Lefi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati fun awọn ọmọ Aaroni, awọn alufa, ti o wà li oko igberiko ilu wọn ni olukuluku ilu, awọn ọkunrin wà nibẹ, ti a pè li orukọ, lati ma fi fun gbogbo awọn ọkunrin ninu awọn alufa, ati fun gbogbo awọn ti a kà ni idile idile ninu awọn ọmọ Lefi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ti àwọn àlùfáà, àwọn ìran ọmọ Árónì, tí ń gbé ni àwọn ilẹ̀ oko lẹ́bàá àwọn ìlú wọn tàbí ní àwọn ìlú mìíràn. A yan àwọn ọkùnrin pẹ̀lú orúkọ láti pín ìlú fún gbogbo ọkùnrin láàárin wọn àti sí gbogbo àwọn tí a kọ sínú ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ baba ńlá àwọn ará Léfì.