2 Chronicles 31:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Hesekaya pín àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́, olukuluku ní iṣẹ́ tirẹ̀. Àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi wà fún ẹbọ sísun, ati ẹbọ alaafia. Àwọn náà ni wọ́n wà fún ati máa ṣe iṣẹ́ ìsìn lẹ́nu ọ̀nà àgọ́ OLUWA, ati láti máa kọrin ọpẹ́ ati ìyìn sí OLUWA.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Hesekiah si yàn ipa awọn alufa, ati awọn ọmọ Lefi nipa ipa wọn, olukuluku gẹgẹ bi iṣẹ-ìsin rẹ̀, awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi fun ẹbọ sisun, ati fun ẹbọ-alafia lati ṣiṣẹ, ati lati dupẹ, ati lati ma yìn li ẹnu-ọ̀na ibudo Oluwa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Heṣekíà fi lé àwọn àlùfáà àti àwọn ará Léfì lọ́wọ́ sí àwọn ìpín olúkúlùkù wọn gẹ́gẹ́ bí isẹ́ wọn gẹ́gẹ́ bí àlùfáà tàbí ará Léfì láti tẹ́ ọrẹ sísun àti ọrẹ ìdàpọ̀, láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ láti fi ọpẹ́ fún àti láti kọ àwọn orin ìyìn ní ẹnu ọ̀nà ibùgbé OLÚWA.