2 Chronicles 31:21 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Gbogbo ohun tí ó ṣe ninu iṣẹ́ ìsìn ilé OLUWA, gẹ́gẹ́ bí òfin ati àṣẹ Ọlọ́run, ati wíwá tí ó wá ojurere Ọlọrun, gbogbo rẹ̀ ni ó ṣe tọkàntọkàn, ó sì dára fún un.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati ninu gbogbo iṣẹ ti o bẹ̀rẹ ninu iṣẹ-ìsin ile Ọlọrun, ati ninu ofin, ati ni aṣẹ, lati wá Ọlọrun, o fi gbogbo ọkàn rẹ̀ ṣe e, o si ṣe rere.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nínú ohun gbogbo tí ó dáwọ́lé níti iṣẹ́ ìsìn nínú ilé Ọlọ́run àti ní ìgbọ́ràn sí òfin àti àwọn àṣẹ. Ó wá Ọlọ́run rẹ̀, ó sì ṣiṣẹ́ tọkàntọkàn. Ó sì ṣe rere.