2 Chronicles 31:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Hesekaya a máa fa ẹran kalẹ̀ ninu agbo ẹran rẹ̀ fún ẹbọ sísun ti àárọ̀ ati ti àṣáálẹ́, ati fún ẹbọ ọjọ́ ìsinmi, ẹbọ oṣù tuntun ati àwọn ẹbọ mìíràn gẹ́gẹ́ bí òfin OLUWA.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọba si fi ipin lati inu ini rẹ̀ sapakan fun ẹbọ sisun, fun ẹbọ sisun orowurọ ati alalẹ, ati ẹbọ sisun ọjọjọ isimi, ati fun oṣù titun, ati fun ajọ ti a yàn, bi a ti kọ ọ ninu ofin Oluwa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọba dá láti ara ohun ìni rẹ̀ fun ọrẹ sísun àárọ̀ àti ìrọ̀lẹ́ àti fún ọrẹ sísun ní ọjọ́ ìsinmi, òṣùpá tuntun àti àsè yíyàn gẹ́gẹ́ bi a ti se kọ ọ́ nínú òfin OLÚWA.