2 Chronicles 31:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọba pàṣẹ fún àwọn tí wọn ń gbé Jerusalẹmu pé kí wọ́n mú ọrẹ tí ó tọ́ sí àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi wa, kí wọ́n lè fi gbogbo àkókò wọn sílẹ̀ láti máa kọ́ àwọn eniyan ní òfin OLUWA.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Pẹlupẹlu o paṣẹ fun awọn enia ti ngbe Jerusalemu lati fi ipin kan fun awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi, ki nwọn ki o le di ofin Oluwa mu ṣinṣin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó pàsẹ fún àwọn ènìyàn tí ń gbé ní Jerúsálẹ́mù láti fi ìpín tí ó yẹ fún àlùfáà fún un àti àwọn ará Léfì, kí wọn kí ó lè fi ara wọn jìn fún òfin OLÚWA.