2 Chronicles 32:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Lẹ́yìn gbogbo nǹkan tí Hesekaya ṣe, tí ó sin OLUWA pẹlu òtítọ́, Senakeribu ọba Asiria wá gbógun ti Juda. Ó dó ti àwọn ìlú olódi wọn, ó lérò pé òun óo jagun gbà wọ́n.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
LẸHIN ti a ti ṣe iṣẹ wọnyi lotitọ, Sennakeribu, ọba Assiria, de, o si wọ̀ inu Juda lọ, o si dótì awọn ilu olodi, o si rò lati gbà wọn fun ara rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lẹ́yìn gbogbo èyí ti Heṣekíà ti fi otítọ́ se, Senakéríbù ọba Ásíríà wá ó sì gbógun ti Júdà. Ó gbógun ti àwọn ìlú ààbò, ó ń ronú láti ṣẹ́gun wọn fún ararẹ̀.