2 Chronicles 32:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó ní ǹjẹ́ wọ́n mọ ohun tí òun ati baba òun ti ṣe sí àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn? Ati pé, ǹjẹ́ àwọn oriṣa àwọn orílẹ̀-èdè náà gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́wọ́ ọba Asiria?
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Enyin kò ha mọ̀ ohun ti emi ati awọn baba mi ti ṣe si gbogbo enia ilẹ miran? awọn oriṣa awọn orilẹ-ède ilẹ wọnni ha le gbà ilẹ wọn lọwọ mi rara?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ṣé ẹ̀yin kò mọ̀ ohun tí èmi àti àwọn bàbá mi ti ṣe sí gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ mìíràn? Ǹjẹ́ àwọn Ọlọ́run tí àwọn orílẹ̀ èdè mìíràn ní agbára láti gba ilẹ̀ wọn kúrò lọ́wọ́ mi?