2 Chronicles 32:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó ní nítorí náà, kí wọn má ṣe jẹ́ kí Hesekaya tàn wọ́n jẹ, tabi kí ó ṣì wọ́n lọ́nà báyìí. Ó ní kí wọn má gbọ́ ohun tí ó ń sọ rárá, nítorí pé kò sí oriṣa orílẹ̀-èdè kan tí ó tó gba àwọn eniyan rẹ̀ lọ́wọ́ òun tabi lọ́wọ́ àwọn baba òun, kí á má wá sọ pé Ọlọrun tiwọn yóo gbà wọ́n lọ́wọ́ òun.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ nitorina, ẹ máṣe jẹ ki Hesekiah ki o tàn nyin jẹ, bẹ̃ni ki o máṣe rọ̀ nyin bi iru eyi, bẹ̃ni ki ẹ máṣe gbà a gbọ́: nitoriti kò si oriṣa orilẹ-ède tabi ijọba kan ti o le gbà enia rẹ̀ lọwọ mi, ati lọwọ awọn baba mi: ambọtori Ọlọrun nyin ti yio fi gbà nyin lọwọ mi?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nísinsinyìí, ẹ má ṣe jẹ́ kí Heṣekáyà ó tàn yín àti sì yín tọ́ sọ́nà báyìí. Ẹ má se gbàá gbọ́, nítorí tí kò sí Ọlọ́run orílẹ̀-èdè mìíràn tàbí ìjọba tí ó ní agbára láti gba àwọn ènìyàn rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ mi tàbí lọ́wọ́ àwọn bàbá mi, mélòómélòó wa ni Ọlọ́run yín tí yóò gbà yín kúrò lọ́wọ́ mi!”