2 Chronicles 32:17 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọba Asiria yìí kọ àwọn ìwé àfojúdi kan sí OLUWA Ọlọrun Israẹli, ó ní, “Gẹ́gẹ́ bí àwọn oriṣa àwọn orílẹ̀-èdè yòókù kò ti lè gba àwọn eniyan wọn kúrò lọ́wọ́ mi, bẹ́ẹ̀ ni Ọlọrun Hesekaya náà kò ní lè gba àwọn eniyan rẹ̀ lọ́wọ́ mi.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O kọ iwe pẹlu lati kẹgan Oluwa, Ọlọrun Israeli, ati lati sọ̀rọ òdi si i, wipe, Gẹgẹ bi awọn oriṣa orilẹ-ède ilẹ miran kò ti gbà awọn enia wọn lọwọ mi, bẹ̃li Ọlọrun Hesekiah kì yio gbà awọn enia rẹ̀ lọwọ mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọba pẹ̀lú sì kọ àwọn ìwé ní bíbú OLÚWA Ọlọ́run Ísírẹ́lì àti ní sísọ èyí ní ìlòdì sí: “Ní gẹ́gẹ́ bí àwọn ọlọ́run àwọn ènìyàn ilẹ̀ mìíràn kò ṣe gba àwọn ènìyàn wọn kúrò lọ́wọ́ mi, Bẹ́ẹ̀ ni Ọlọ́run Heṣekáyà kì yóò gba àwọn ènìyàn rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ mi.”
Recommended Reading