2 Chronicles 32:21 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA bá rán angẹli kan lọ pa gbogbo akọni ọmọ ogun, ati àwọn ọ̀gágun ati àwọn olórí ogun Asiria ní ibùdó wọn. Nítorí náà, pẹlu ìtìjú ńlá ni Senakeribu fi pada lọ sí ìlú rẹ̀. Nígbà tí ó wọ inú ilé oriṣa lọ, àwọn kan ninu àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin bá fi idà pa á.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Oluwa si rán Angeli kan, ẹniti o pa gbogbo awọn alagbara ogun, ati awọn aṣãju, ati awọn balogun ni ibudo ọba Assiria. Bẹ̃li o fi itiju pada si ilẹ on tikararẹ̀. Nigbati o si wá sinu ile oriṣa rẹ̀, awọn ti o ti inu ara rẹ̀ jade si fi idà pa a nibẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA sì ran ańgẹ́lì tí ó pa gbogbo àwọn oko oníjà àti àwọn adarí àti àwọn ìjòyè tí ó wà nínú àgọ́ ọba Ásíríà run. Bẹ́ẹ̀ ni ó padà sí ilẹ̀ rẹ̀ ní ìtìjú. Nígbà tí ó sì lọ sínú ilé ọlọ́run rẹ̀, díẹ̀ nínú àwọn ọmọ rẹ̀ gé e lulẹ̀ pẹ̀lú idà.