2 Chronicles 32:23 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọpọlọpọ eniyan mú ẹ̀bùn wá fún OLUWA ní Jerusalẹmu, wọ́n sì mú ẹ̀bùn olówó iyebíye wá fún Hesekaya, ọba Juda. Láti ìgbà náà lọ, àwọn orílẹ̀-èdè káàkiri bẹ̀rẹ̀ sí kókìkí rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọ̀pọlọpọ si mu ẹ̀bun fun Oluwa wá si Jerusalemu, ati ọrẹ fun Hesekiah, ọba Juda: a si gbé e ga loju gbogbo orilẹ-ède lẹhin na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọ̀pọ̀ mú ọrẹ wá sí Jérúsálẹ́mù fún OLÚWA àti àwọn ẹ̀bùn iyebíye fún Heṣekáyà ọba Júdà. Láti ìgbà náà lọ gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè ni ó kàá sí.