2 Chronicles 32:25 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
ṣugbọn Hesekaya ṣe ìgbéraga, kò fi ẹ̀mí ìmoore hàn fún ohun tí Ọlọrun ṣe fún un. Nítorí náà, inú bí OLUWA sí àtòun ati Juda ati Jerusalẹmu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn Hesekiah kò si tun pada san gẹgẹ bi ore ti a ṣe fun u: nitoriti ọkàn rẹ̀ gbega: nitorina ni ibinu ṣe wà lori rẹ̀, lori Juda, ati lori Jerusalemu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n ọkàn Heṣekáyà ṣe ìgbéraga, kò sì kọbi ara síi inú rere tí a fi hàn án. Nítorí náà, ìbínú OLÚWA wà lórí rẹ̀ àti lóri Júdà àti Jérúsálẹ́mù.