2 Chronicles 32:30 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Hesekaya náà ló dí ẹnu odò Gihoni ní apá òkè, ó ya omi rẹ̀ wọ ìhà ìwọ̀ oòrùn ìlú Dafidi. Hesekaya sì ń ní ìlọsíwájú ninu gbogbo iṣẹ́ rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Hesekiah kanna yi li o dí ipa-omi ti o wà li òke Gihoni pẹlu, o si mu u wá isalẹ tara si iha iwọ-õrun ilu Dafidi. Hesekiah si ṣe rere ni gbogbo iṣẹ rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Heṣekíà ni ó dí ojú ìṣúra apá òkè ti orísun Gíhónì. Ó sì gbe gba ìsàlẹ̀ sí ìhà ìwọ oòrùn ìlú ńlá ti Dáfídì. Ó ṣe àṣeyọrí sí rere nínu gbogbo ohun tí ó dáwọ́lé.