2 Chronicles 32:31 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí àwọn olórí ilẹ̀ Babiloni ranṣẹ sí i láti mọ̀ nípa ohun ìyanu tí ó ṣẹlẹ̀ ní ilẹ̀ náà, Ọlọrun fi sílẹ̀ láti dán an wò, kí Ọlọrun lè mọ gbogbo ohun tí ó wà lọ́kàn rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn niti awọn ikọ̀ awọn ọmọ-alade Babeli, ti nwọn ranṣẹ si i, lati bère ohun-iyanu ti a ṣe ni ilẹ na, Ọlọrun fi i silẹ lati dán a wò, ki o le mọ̀ ohun gbogbo ti o wà li ọkàn rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n nígbà tí ara àwọn oníṣẹ́ ọba wá láti Bábílónì láti bi í lérè nípa àmìn ìyanu tí ó sẹlẹ̀ nì, Ọlọ́run fi sílẹ̀ láti dán an wò àti láti mọ gbogbo nǹkan tí ó wà lọ́kàn rẹ̀.