2 Chronicles 32:33 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí Hesekaya kú, wọ́n sin ín sí ara òkè, ninu ibojì àwọn ọmọ Dafidi. Gbogbo àwọn eniyan Juda ati ti Jerusalẹmu ṣe ẹ̀yẹ fún un. Manase, ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Hesekiah si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, nwọn si sin i ninu iboji awọn ọmọ Dafidi: ati gbogbo Juda ati awọn ti ngbe Jerusalemu ṣe ẹyẹ fun u ni iku rẹ̀. Manasse ọmọ rẹ̀, si jọba ni ipò rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Heṣekáyà sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀. A sì sin-ín sórí òkè níbi tí àwọn ibojì àwọn àtẹ̀lé Dáfídì wà. Gbogbo Júdà àti àwọn ènìyàn Jérúsálẹ́mù ni ó bu ọlá fún un nígbà tí ó kú. Mánásè ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.