2 Chronicles 32:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọba yan àwọn òṣìṣẹ́ láti mọ gbogbo àwọn odi tí ó wó lulẹ̀, ati láti kọ́ ilé ìṣọ́ sí orí wọn. Wọ́n tún mọ odi mìíràn yípo wọn. Ó tún Milo tí ó wà ní ìlú Dafidi ṣe kí ó fi lágbára síi, ó sì pèsè ọpọlọpọ nǹkan ìjà ati apata.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O mu ara rẹ̀ le pẹlu, o si mọ gbogbo odi ti o ti ya, o si gbé e ga de awọn ile-iṣọ, ati odi miran lode, o si tun Millo ṣe ni ilu Dafidi, o si ṣe ọ̀kọ ati apata li ọ̀pọlọpọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ó ṣiṣẹ́ gidigidi ní títún gbogbo ìtorí ara ògiri tí ó ti bàjẹ́ ṣe, ó sì ń kọ́ àwọn ilé iṣẹ́ gíga sókè rẹ̀. Ó kọ́ ògiri mìíràn sí ìta ìyẹn. Ó sì rán ibi ìfẹ̀yìntì lọ́wọ́ pẹ̀lú ibi ìtẹ́jú ilé níti ìlú ńlá Dáfídì. Ó ṣe ọ̀pọ̀ iye ohun ìjà àti àwọn àpáta.