2 Chronicles 32:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Ẹ múra, ẹ ṣọkàn gírí. Ẹ má bẹ̀rù, ẹ má sì jáyà níwájú ọba Asiria ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ bí wọ́n tilẹ̀ pọ̀; nítorí agbára ẹni tí ó wà pẹlu wa ju ti àwọn tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ lọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹ mu ara le, ki ẹ si ṣe onigboya, ẹ má bẹ̀ru, bẹ̃ni ki aiya ki o máṣe fò nyin nitori ọba Assiria, tabi nitori gbogbo ọ̀pọlọpọ enia ti o wà pẹlu rẹ̀; nitori awọn ti o pẹlu wa jù awọn ti o pẹlu rẹ̀ lọ:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ẹ jẹ́ alágbára, àti kí ẹ sì ní ìgboyà. Ẹ má se bẹ̀rù tàbí ní ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn nítorí tí ọba Ásíríà àti ọ̀pọ̀ ọmọ-ogun pẹ̀lú rẹ̀, nítorí tí agbára ńlá wà pẹ̀lú wa ju òun lọ.