2 Chronicles 32:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Agbára ti ẹran ara ni àwọn ọmọ ogun tirẹ̀ ní, ṣugbọn OLUWA Ọlọrun ni ó wà pẹlu wa láti ràn wá lọ́wọ́ ati láti jà fún wa.” Ọ̀rọ̀ tí Hesekaya ọba Juda sọ sì fi àwọn eniyan rẹ̀ lọ́kàn balẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Apa ẹran-ara li o pẹlu rẹ̀, ṣugbọn Oluwa Ọlọrun wa li o pẹlu wa lati ràn wa lọwọ, ati lati jà ogun wa. Awọn enia na si gbẹkẹ wọn le ọ̀rọ Hesekiah, ọba Juda.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Agbára ẹran ara nìkan ni ó wà pẹ̀lú rẹ̀ ṣùgbọ́n, pẹ̀lú wa ni Ọlọ́run láti ràn wá lọ́wọ́ àti láti ja ìjà wa.” Àwọn ènìyàn sì ní ìgboyà láti ara ohun tí Hesekía ọba Júdà wí.

Recommended Reading