2 Chronicles 32:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Lẹ́yìn èyí, nígbà tí Senakeribu ati àwọn ogun rẹ̀ gbógun ti Lakiṣi, ó ranṣẹ sí Hesekaya ọba Juda ati àwọn ará Juda tí wọ́n wà ní Jerusalẹmu pé,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Lẹhin eyi ni Sennakeribu, ọba Assiria, rán awọn iranṣẹ si Jerusalemu, (ṣugbọn on tikararẹ̀ dótì Lakiṣi ati gbogbo ogun rẹ̀ pẹlu rẹ̀) sọdọ Hesekiah, ọba Juda ati sọdọ gbogbo Juda ti o wà ni Jerusalemu wipe,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lẹ́yìn ìgbà tí Senakéríbù ọba Ásíríà àti gbogbo àwọn ogun rẹ̀ ń gbógun sí Lákíṣì. Ó rán àwọn ìjòyè rẹ̀ sí Jérúsálẹ́mù pẹ̀lú iṣẹ́ yí fún Heṣekáyà ọba Júdà àti fún gbogbo àwọn ènìyàn Júdà tí ó wà níbẹ̀: