2 Chronicles 33:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Lẹ́yìn náà ó mọ odi ìta sí ìlú Dafidi, ní apá ìwọ̀ oòrùn Gihoni, ní àfonífojì, ati sí ẹnubodè ẹja; ó mọ ọ́n tí ó ga yípo Ofeli. Ó kó àwọn ọ̀gágun sinu àwọn ìlú olódi ní Juda.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ lẹhin eyi, o mọ odi kan lẹhin ilu Dafidi, niha ìwọ-õrun Gihoni, li àfonifoji, ani li atiwọ ẹnu-bode ẹja, o si yi Ofeli ka, o si mọ ọ ga soke gidigidi, o si fi balogun sinu gbogbo ilú olodi Juda wọnni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lẹ́yìn èyí, ó tún ìta ògiri ìlú ńlá Dáfídì kọ́. Ìhà ìwọ̀ oòrùn orísun Gíhónì ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, ní jìnnà réré bí ẹnu ọ̀nà àbáwọlé ẹja àti yíyí orí òkè Ófélì; ó se é ní gíga díẹ̀. Ó mú àwọn alákòóso ológun wà ní ìdúró nínú gbogbo àwọn ìlú ńlá olódi ní Júdà.