2 Chronicles 33:15 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó kó àwọn oriṣa ati àwọn ère kúrò ninu ilé OLUWA, ati gbogbo ojúbọ oriṣa tí ó kọ́ sórí òkè níbi tí ilé OLUWA wà, ati àwọn tí wọ́n kọ́ káàkiri gbogbo ìlú Jerusalẹmu. Ó da gbogbo wọn sẹ́yìn odi ìlú.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si kó awọn àjeji ọlọrun ati ere kuro ni ile Oluwa, ati gbogbo pẹpẹ ti o ti tẹ́ lori òke ile Oluwa ati ni Jerusalemu, o si kó wọn danu kuro ni ilu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó pa gbogbo àwọn Ọlọ́run àjòjì run. Ó sì hú gbogbo àwọn ère kúrò nínú ilé OLÚWA, pẹ̀lú gbogbo àwọn pẹpẹ tí ó ti kọ́ ní òkè ilé OLÚWA àti ní Jérúsálẹ́mù; ó sì kó wọn jáde kúrò nínú ìlú.