2 Chronicles 33:19 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Adura rẹ̀ sí Ọlọrun, ati bí Ọlọrun ṣe dá a lóhùn, àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ati aiṣododo rẹ̀, wà ninu ìwé Ìtàn Àwọn Aríran. Bẹ́ẹ̀ náà ni gbogbo ibi tí ó kọ́ pẹpẹ ìrúbọ rẹ̀ sí, àwọn ère tí ó gbẹ́ fún Aṣera, ati àwọn ère tí ó ń sìn kí ó tó ronupiwada.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Adura rẹ̀ na pẹlu, bi Ọlọrun ti gbọ́ ẹ̀bẹ rẹ̀, ati gbogbo ẹ̀ṣẹ rẹ̀, ati irekọja rẹ̀ ati ibi ti o gbe kọ́ ibi giga wọnni ti o si gbé ere-oriṣa kalẹ, ati awọn ere yiyá, ki a to rẹ̀ ẹ silẹ, kiye si i, a kọ wọn sinu iwe itan Hosai.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àdúrà rẹ̀ àti bí inú Ọlọ́run ṣe dùn sí àdúrà rẹ̀ àti gbogbo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ àti àìsòótọ́ àti àwọn ipò níbi tí ó kọ́ àwọn ibi gíga sí, ó sì gbé àwọn òpó Áṣérà àti àwọn òrìṣà kí ó tó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, gbogbo rẹ̀ ni a kọ sínu ìwé ìrántí àwọn aríran.