2 Chronicles 33:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Gbogbo ibi ìrúbọ tí Hesekaya, baba rẹ̀ ti wó lulẹ̀ ni ó tún kọ́. Ó tẹ́ pẹpẹ fún Baali, ó sì ri àwọn òpó fún Aṣera. Ó ń bọ àwọn ìràwọ̀, ó sì ń sìn wọ́n.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori ti o tun kọ́ ibi giga wọnni ti Hesekiah baba rẹ̀, ti wó lulẹ, o si gbé pẹpẹ wọnni soke fun Baalimu, o si ṣe ere oriṣa, o si mbọ gbogbo ogun ọrun, o si nsìn wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó tún kọ́ àwọn ibi gíga tí baba rẹ̀ Heṣekáyà ti fọ́ túútúú. Ó sì gbé àwọn pẹpẹ dìde fún àwọn Báálì ó sì ṣe àwọn òpó Áṣérà. Ó foríbalẹ̀ fún gbogbo àwọn ogun ọ̀run ó sì sìn wọ́n.