2 Chronicles 33:6 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó fi àwọn ọmọ rẹ̀ rú ẹbọ sísun ní àfonífojì ọmọ Hinomu. Ó ń lo àfọ̀ṣẹ, ó ń woṣẹ́, a sì máa lọ sọ́dọ̀ àwọn abókùúsọ̀rọ̀. Ó dẹ́ṣẹ̀ sí OLUWA tóbẹ́ẹ̀ tí inú OLUWA fi bẹ̀rẹ̀ sí ru.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si mu ki awọn ọmọ rẹ̀ ki o kọja lãrin iná àfonifoji ọmọ Hinnomu: ati pẹlu o nṣe akiyesi afọṣẹ, o si nlò alupayida, o si nṣe ajẹ́, o si mba okú lò, ati pẹlu oṣó: o ṣe buburu pupọ̀ li oju Oluwa lati mu u binu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó fi àwọn ọmọ rẹ̀ rúbọ nínú iná ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Bẹni-Hínómù, ó ń ṣe oṣó, àfọ̀ṣẹ, ìsàjẹ́ pẹ̀lú bíbéèrè lọ́dọ̀ àwọn abókúsọ̀rọ̀, àti ẹlẹ́mìí. O se ọ̀pọ̀ ohun búburú ní ojú OLÚWA láti mú un bínú.