2 Chronicles 33:7 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó gbé ère oriṣa tí ó gbẹ́ wá sí ilé Ọlọrun, ilé tí Ọlọrun ti sọ nípa rẹ̀ fún Dafidi ati Solomoni, ọmọ rẹ̀ pé, “Ninu ilé yìí ati ní Jerusalẹmu tí mo ti yàn láàrin àwọn ẹ̀yà Israẹli mejeejila ni wọn yóo ti máa sìn mí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si gbé ere gbigbẹ kalẹ, ere ti o ti yá sinu ile Ọlọrun, niti eyiti Ọlọrun ti sọ fun Dafidi ati Solomoni, ọmọ rẹ̀, pe, Ninu ile yi, ati ni Jerusalemu ti emi ti yàn ninu gbogbo ẹ̀ya Israeli, li emi o fi orukọ mi si lailai:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó mú ère gbígbẹ́ tí ó ti gbẹ́ ó sì gbé e sínú ilé OLÚWA, ní èyí tí Ọlọ́run ti sọ fún Dáfídì àti sí ọmọ rẹ̀ Solómónì, “Nínú ilé OLÚWA yìí àti ní Jérúsálẹ́mù, tí mo ti yàn kúrò nínú gbogbo àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì, èmi yóò fi orúkọ mi síbẹ̀ títí láé.